Help Center

< All Hymns
Print Hymn Lyric

1. Oluṣ’agutan enia Rẹ

ORIN IKINNI …………………………………………………..C.M.
Agọ Rẹ wonni ti li ẹwa to, Oluwa awọn
ọmọ ogun – Orin Dafidi 84:1

1 f Oluṣ’agutan enia Rẹ
Nbi, f’ara Rẹ han wa,
B’O ti fun wa n’ile adura
Jẹ k’ọkan wa gbadua

2 mf Fi ami ifẹ Rẹ han wa
Sọ ireti wa ji
Sẹ ’ri ’bukun Rẹ s’ori wa
K’awa le ma yin Ọ

3 mf N’ile yi k’alafia mimọ
Ifẹ, iṣọkan gbe!
F’itunnu f’ọkan to daru
W’ọkan ailera san

4 mf F’eti igbọ, oju ‘riran
F’aya ‘gbaṣe, fun wa;
Tan imọlẹ Rẹ la t’oke
K’a dagba l’or’ọfẹ

5 mf K’a fi gbagbọ gba ọrọ Rẹ
K’a f’igbagbọ bere
Niwaju Iwọ Oluwa
K’a gbẹru ṣoro wa. ….Amin

Table of Contents

Price Based Country test mode enabled for testing United States (US). You should do tests on private browsing mode. Browse in private with Firefox, Chrome and Safari